Èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ Rẹ.@Saamu 119:57

John E. Bode, 1868 (O Jesus, I Have Promised). .

Day of Rest James W. Elliott, 1874 (🔊 pdf nwc).

aworan
John E. Bode
1816–1874

Mo ti seleri Jesu,
Lati sin O dopin;
Ma wa lodo mi titi,
Baba mi Ore mi.
Emi k’yo beru ogun,
B’Iwo ba sun mo mi,
Emi ki y’o si sina,
B’O ba fona han mi.

Je ki n mo p’O sunmo mi,
’Tori’baje aiye;
Aiye fe gba okan mi,
Aiye fe tan mi je,
Ota yi mi ka,kiri,
Lode ati ninu;
Sugbon Jesu, sunmo mi,
Dabobo okan mi.

Je ki emi k’ o ma gbo,
Ohun Re, Jesu mi,
Ninu igbi aiye yi,
Titi nigbagbogbo.
So k’ o f’ okan mi bale,
Teri okan mi ba;
So k’ emi le gbo Tire,
’Wo Olutoju mi.

’Wo ti se ’leri Jesu,
F’awon t’ o tele O,
Pe ibikibi t’O wa,
Lawon yio si wa;
Mo ti se ’leri Jesu,
Lati sin O dopin.
Je ki n ma to O lehin,
Baba mi, Ore mi.

Je ki n ma ri ’pase Re,
Ki n le ma tele O;
Agbara Re nikan ni,
Ti m’ ba le tele O:
To mi, pe mi, si fa mi
Di mi mu de opin,
Si gba mi si odo Re,
Baba mi, Ore mi.