Èmi wa pelu yin nigba gbogbo, titi o fi di ipari akoko igbe aye yi.@Matteu 28:20
portrait
Josiah J. Ransome-Kuti
1855–1930

Je­re­mi­ah E. Ran­kin, 1880 (God Be with You Till We Meet Again). Itu­mọ ni­pasẹ (ṣee ṣe) Jo­si­ah Jes­se Ran­some-Ku­ti (1855–1930).

William G. Tomer (🔊 pdf nwc).

portrait
Jeremiah E. Rankin
1828–1904

K’Olorun so o k’a tun pade!
Ki imoran Re gbe o ro,
K’o ka o mo aguntan Re,
K’Olorun so wa ka tun pade!

Egbe

K’a pade…k’a pade!
K’a pade l’ ese Jesu:
K’a pade…k’a pade!
K’Olorun so o, k’a tun pade.

K’Olorun so o, k’a tun pade!
K’ O f’iye Re dabobo o,
K’ O ma pese fun aini re,
K’Olorun so o k’a tun pade!

Egbe

K’Olorun so o, k’a tun pade!
Nigbat’ ewu ba yi o ka,
K’ owo ife Re gba o mu,
K’ Olorun so o, ka tun pade!

Egbe

K’ Olorun so o, ka tun pade!
K’O fi ife rado bo o,
K’ O pa oro iku fun o,
K’Olorun so wa, ka tun pade!

Egbe