Nitori ti awa gbeke le o, li oruko re li awa nto opopo yi lo.@2 Kronika 14:11
aworan
Charles Wesley (1707-1788)

Charles Wesley, 1749 (Forth in Thy Name, O Lord); a ko mo eniti to seitumo.

Ralph Harrison, 1784 (🔊 PDF nwc).

Oluwa mi, mo njade lo,
Lati se ise ojo mi;
Iwo nikan l’emi o mo
L’oro l’ero, ati n’ise.

Ise t’o yan mi, l’anu Re
Je ki nle se tayotayo;
Ki nr’oju Re ni ise mi,
k’emi si le f’ife Re han.

Dabobo mi lowo ’danwo,
K’o pa okan mimo kuro
L’owo aniyan aiye yi,
Ati gbogbo ifekufe.

Iwo t’oju Re r’okan mi,
Ma wa low’otun mi titi,
Ki mm sise lo l’ase Re,
Ki nf’ise mi gbogbo fun O.

Je ki nreru Re t’o fuye
Ki mma sora nigbagbogbo;
Ki mma f’oju si nkan t’orun,
Ki nsi mura d’ojo ogo.

Ohunkohun t’o fi fun mi
Je ki nle lo fun ogo Re
Ki nfayo sure ije mi
Ki mba O rin titi d’orun.