Wọ́n dá majẹmu pé àwọn yóo máa sin Oluwa lọrun baba àwọn tọkàntọkàn àwọn.@Kronika Keji 15:12
portrait
Edward F. Rimbault (1816-1876)

Philip Doddridge, 1883 (O Happy Day, That Fixed My Choice). .

A ko mo olupilese orin; sugbon egbe je ti Edward F. Rimbault, 1854 (🔊 pdf nwc).

aworan
Philip Doddridge (1702-1751)

Ojo nla l’ojo ti mo yan
Olugbala l’Olorun mi;
O ye ki okan mi ma yo,
K’o si ro ihin na ka ‘le.

Egbe

Ojo nla l’ojo na!
Ti Jesu we ese mi nu
O ko mi ki nma gbadura
Ki nma sora ki nsi ma yo
Ojo nla l’ojo na!
Ti Jesu we ese mi nu.

Ise igbala pari na,
Mo di t’Oluwa mi loni;
On l’o pe mi ti mo si je,
Mo f’ayo jipe mimo na.

Egbe

Eje mimo yi ni mo je
F’enit ’o ye lati feran;
Je k’orin didun kun ’le Re,
Nigba mo ba nlo sin nibe.

Egbe

Simi, aiduro okan mi,
Simi le Jesu Oluwa;
Tani je wipe aiye dun
Ju odo awon angeli?

Egbe

Enyin orun gbo eje mi;
Eje mi ni ojojumo,
Em’o ma so dotun titi
Iku y’o fi mu mi re ’le.

Egbe