Eniti o fi on tikalare fun ese wa, ki o le gba wa kuro ninu aiye buburu isisiyi, gege bi ife Olorun ati Baba wa: Eniti ogo wa fun lai ati lailai. Amin.@Galatia 1:4-5
aworan
Fanny Crosby (1820-1915)

Fanny Crosby, 1875 (To God Be the Glory); a ko mo eniti to seitumo.

W. Howard Doane (🔊 pdf nwc).

aworan
W. Howard Doane (1832-1915)

Ogo ni f’Oluwa, to se ohun nla;
Ifelo mu k’o fun wa ni Omo Re,
Eniti O f’emi Re lele fese wa,
To si silekun iye sile fun wa.

Egbe

Yin Oluwa, yin Oluwa,
F’Iyin fun Oluwa!
Yin Oluwa, yin Oluwa,
E yo ni waju Re!
K’a to baba wa lo, L’oruko Jesu,
Jek’a jo f’ogo fun Onise ’yanu.

Irapada kikun, ti eje Re ra,
F’enikeni t’ogba ileri Re gbo;
Enit’o buruju boba le gbagbo,
Lojukanna y’ori idari gba.

Egbe

O s’ohun nla fun wa, o da wa l’ola.
Ayo wa di kikun ninu Omo Re;
Ogo ati ewa Irapada yi
Y’oya wa lenu ’gbat’a ba ri Jesu.

Egbe