Ati bi a ti ni alufa giga lori ile Olorun; Eje ki a fi otito okan sunmo tosi ni ekun igbagbo, ki a si we okan wa mo kuro ninu eri-okan buburu, ki a si fi omi mimo we ara wa nu.@Heberu 10:21-22
aworan
Phoebe P. Knapp (1839-1908)

Fanny Crosby, 1873 (Blessèd Assurance); a ko mo eniti to seitumo.

Phoebe P. Knapp (🔊 pdf nwc).

aworan
Fanny Crosby (1820-1915)

Oda mi loju, mo ni Jesu!
Itowo adun oorun l’eyi je!
Mo di ajogun igbala nla,
Eje Re we mi, a tun mi bi.

Egbe

Ngo so itan na, ngo korin na,
Ngo yin Olugbala mi titi;
Ngo so itan na, ngo korin na,
Ngo yin Olugbala mi titi.

Ngo teriba fun tayotayo,
Mo le ri iran ogo bibo Re;
Angeli nmu ihin didun wa
Ti ife at’anu Re si mi.

Egbe

Ngo teriba fun, ngo simi le
Mo di ti Jesu, Mo d’eni ’bukun,
Ngo ma sora, ngo si gbadura,
Ki ore Re ma fi mi sile.

Egbe