Ìyè ainipẹkun náà ni pé, kí wọ́n mọ̀ ọ́, ìwọ Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo, kí wọ́n sì mọ Jesu Kristi ẹni tí o rán níṣẹ́.@1 Tessalonika 4:16-17
portrait
James Montgomery (1771-1854)

James Montgomery, Poet’s Portfolio 1835 (Forever with the Lord). .

Isaac B. Woodbury, 1852, & Arthur S. Sullivan, 1874 (🔊 pdf nwc).

portrait
Isaac B. Woodbury (1819-1858)

Lai lodo Oluwa!
Amin, beni k’o ri,
Iye wa ninu oro na,
Aiku ni titi lai,
Nihin ninu ara,
Mo sako jina si;
Sibe alale ni mo nfi,
Ojo kan sunmole!

Ile Baba loke,
Ile okan mi ni;
Emi nfi oju igbagbo
Wo bode wura re!
Okan mi nfa pipo,
S’ ile na ti mo fe,
Ile didan t’ awon mimo
Jerusalem t’ orun.

Awosanma dide,
Gbogbo ero mi pin;
Bi adaba Noa, mo nfo
Larin iji lile.
Sugbon sanma kuro,
Iji si rekoja,
Ayo ati alafia
Si gba okan mi kan.

L’ oro ati l’ ale
L’ osan ati l’ oru,
Mo ngbo orin orun, bori
Rudurudu aiye,
Oro ajinde ni,
Hiho isegun ni,
Lekan si, Lai lod’ Oluwa.
Amin, beni ko ri.