Ati laisi itajesile, ko le si idariji.@Heberu 9:22
retrato
Robert Lowry (1826-1899)

Robert Lowry, 1876 (Nothing but the Blood); a ko mo eniti to seitumo (🔊 pdf nwc).

Ki lo le w’ese mi nu,
Ko so, leyin eje Jesu;
Ki l’tun le wo mi san,
ko si, leyin eje Jesu.

Egbe

A! eje yebiye
T’o mu mi fun bi sno
Ko s’isun miran mo,
Ko si lehin eje Jesu

Fun ’wenumo mi, nko ri
Nkan mi, lehin eje Jesu;
ohun ti mo gbekele,
Fun ’dariji, l’eje Jesu.

Egbe

Etutu f’ese ko si,
Ko si, lehin eje Jesu;
Ise rere kan ko si,
Ko si, lehin eje Jesu.

Egbe

Gbogbo igbekele mi,
Ireti mi, l’eje Jesu;
Gbogbo ododo mi ni
Eje, kiki eje Jesu

Egbe