Emi li eniti o mbe laye, ti o si ti ku; si kiyesi i, emi si mbe laye si i titi lai, Amin; mo si ni kokoro iku at ti ipo-oku.@Ifihan 1:18
aworan
Christian F. Gellert (1715-1769)

Christian F. Gellert, 1751 (Jesus lebt, mit ihm auch ich); a ko mo eniti to seitumo.

Henry J. Gauntlett, 1852 (🔊 pdf nwc).

aworan
Henry J. Gauntlett (1805-1876)

Jesu ye, titi aiye
Eru iku ko ba ni mo;
Jesu ye; Nitorina
Isa oku ko n’ipa mo.
Alleluya!

Jesu ye; lat’oni lo
Iku je ona si iye;
Eyi y’o je ‘tunu wa
‘Gbat’ akoko iku ba de.
Alleluya!

Jesu ye; fun wa l’o ku
Nje Tire ni a o ma se;
A o f’okan funfun sin,
A o f’ ogo f’Olugbala.
Alleluya!

Jesu ye; eyi daju
Iku at’ipa okunkun
Ki y’o le ya ni kuro
Ninu ife nla ti Jesu
Alleluya!

Jesu ye; gbogbo ‘joba
L’orun, li aiye, di tire;
E je ki a ma tele,
ki a le joba pelu Re.
Alleluya!