Ayo mbo lowuro.@Orin Dafidi
aworan
Frederick W. Faber (1814-1863)

Frederick W. Faber, 1854 (Hark! Hark, My Soul!); a ko mo eniti to seitumo.

Henry T. Smart, 1868 (🔊 pdf nwc).

aworan
Henry T. Smart (1813-1879)

Gbo okan mi, bi angeli ti nkorin
Yika orun ati yika aiye
E gbo bi oro orin won ti dun to
Ti nso gbati ese ki y’o si mo.

Egbe

Angeli Jesu, angel’ mole
Nwon nkorin ayo pade ero lona

B’a si ti nlo, bee l’a si ngo orin won
Wa, arale, Jesu l’o ni k’e wa
L’okunkun ni a ngo orin didun won
Ohun orin won ni nfonahan wa

Egbe

Ohun Jesu ni a n gbo l’ona rere
Ohun naa ndun b’agogo y’aye ka
Egbegberun awon t’o gbo ni si mbo
Mu won w’odo Re, Olugbala wa

Egbe

Isimi de, lehin ise on aare
Ojumo mo, lehin okun aye;
Irin ajo pari, f’awon alare
Nwon si ti d’orun ibi isimi:

Egbe

Ma korin nso eyin angeli rere
E ma korin didun k’a ba ma gbo;
Tit’ao fi nu omije oju wa nu
Ti a’o si ma yo titi lailai.

Egbe