Nitorinaa mo fi iyonu Olorun be yin, ara, ki eyin ki o fi ara yin fun Olorun li ebo aaye, mimo, itewogba, eyi ni ise-isin yin ti o tona.@Romu 12:1
aworan
John B. Dykes (1823-1876)

Frances R. Havergal, 1874 (Take My Life and Let It Be); a ko mo eniti to seitumo.

John B. Dykes, 1862 (🔊 PDF nwc).

aworan
Frances R. Havergal (1836-1879)

Gba aiye mi oluwa,
Mo ya si mimo fun O
Gba gbogbo akoko mi
Ki nwon kun fin iyin Re.

Gba owo mi, k’o si je
Ki nma lo fun ife Re;
Gba ese mi, k’o si je
Ma jise fun O titi

Gba ohun mi, je ki nma
Korin f’oba mi titi;
Gba ete mi, je ki wom
ma jise fun o titi.

Gba wure, fadaka mi
Okan nki o da duro;
Gba ogbon mi, ko si lo
Gege bi o ba ti fe.

Gba ’fe mi. fi se Tire;
Kio tun je temi mo;
Gb’ okan mi, Tire n’ ise
Ma gunwa nibe titi.

Gba ’feran mi, Oluwa
mo fi gbogbo re fun O
Gb’emi papa; lat’ one
Ki’m je Tire titi lai.