Mary E. Servoss (1849-1906) (Be Glad in the Lord). .

James McGranahan (1840-1907) (🔊 pdf nwc).

retrato
James McGranahan (1840-1907)

E yo ninu Oluwa, E yo
Eyin t’okan re se dede
Eyin t’o ti yan Oluwa
L’ibanuje ati aro lo.

Egbe

E yo, e yo
E yo nin’Oluwa e yo
E yo, E yo
E yo nin’Oluwa e yo.

E yo, to r’oun l’Oluwa
L’aye ati l’orun pelu
Oro re bor’ohun gbogbo
O l’agbara l’ati gbala.

Egbe

Gba t’a ba n ja ija rere
Ti ota fere bori yin
Ogun Olorun t’a ko ri
Poju awon ota yin lo.

Egbe

B’okunkun ti le yi o ka
Pelu isudede gbogbo
Mase je k’Okan re damu
Sa gbekel’Oluwa d’opin.

Egbe

E yo ninu Oluwa, e yo
E k’orin iyin re kikan
Fi duru ati ohun ko
Halleluyah l’ohun goro.

Egbe