Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa: nitoriti o ṣeun; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai@O. Daf 136:1

John Milton, 1623 (Let Us with a Gladsome Mind). .

Monkland John Antes, 1790 (🔊 pdf nwc).

aworan
John Milton (1608-1674)

E je k’a f’inu didun,
Yin Oluwa olore;

Egbe

Anu Re, o wa titi,
Lododo dajudaju.

On, nipa agbara Re,
F’imole s’aiye titun;

Egbe

O mbo awon alaini,
Ati gbogbo alaye;

Egbe

O bukun ayanfe Re,
Li aginju iparun;

Egbe

E je ka f’inu didun
Yin Oluwa olore

Egbe