E ma se beru, bee ni ki e ma se f’oya nitori opolopo eniyan yii; nitori ogun naa kii se tiyin bikose ti olorun.@2 Kronika 20:15
aworan
Sabine Baring-Gould
1834–1924
National Portrait Gallery

button

Sabine Baring-Gould, 1865 (Onward, Christian Soldiers). .

Arthur S. Sullivan, 1871 (🔊 pdf nwc).

aworan
Arthur S. Sullivan (1842–1900)

E maa te siwaju, Kriatian ologun
Maa tejumo mo Jesu t’o mbe niwaju;
Kristi Oluwa wa niBalogun wa
Wo! asia re wa niwaju ogun.

Egbe

E ma te siwaju Kristain ologun
Sa tejumo Jesu t’o mbe niwaju.

Ni oruko Jesu ogun esu sa,
Nje Kristian ologun, ma nso si segun;
Orun apadi mi ni hiho iyin
Ara gbohun yin ga, gb’orin yin soke.

Egbe

Bi egbe ogun nla, n’Ijo Olorun,
Ara, a nrin l’ona t’awon mimo
A ko ya wa n’ipa, egebe kan ni wa
Okan L’eko n’ife ati n’ireti.

Egbe

Ite at’ijoba wonyi le parun,
Sugbon Ijo jesu y’o wa titi lai,
Orun apadi ko le bor’ ijo yi
A n’ileri Kristi, eyi ko le ye.

Egbe

E ma ba ni kalo, eyin eyan;
D’ohun yin po mo, lorin isegun,
Ogo, iyin, ola fun Kristi Oba
Eyi ni y’o ma je orin wa titi.

Egbe