Nitoripe kii se eje ati eran-ara li awa mba jijakadi, sugbon awon ijoye, awon olala, awon alase ibi okunkun aye yi, ati awon emi buburu ni oju orun@Efesu 6:12
aworan
George Duffield (1818-1888)

George Duffield, Jr., 1858 (Stand Up, Stand Up for Jesus); a ko mo eniti to seitumo.

George J. Webb, 1830 (🔊 pdf nwc).

aworan
George J. Webb (1803-1887)

Duro, duro fun Jesu,
Eyin om’ogun Krist:
Gbe asia Re soke
A ko’gbodo fe ku;
Lati segun de ’segun
Ni y’o ma to ogun Re;
Tit’ao segun gbogb’ota,
Ti Krist yo j’Oluwa

Duro, duro fun Jesu
F’eti s’ohun ipe
Jade lo s’oju ija
L’oni ojo nla Re:
Enyin akin ti nja fun
Larin ainiye ota,
Nu ewu en’ igboya
Dojuko agbara.

Duro, duro fun Jesu,
Duro l’agbara Re
Ipa enia ko to
Ma gbekele tire:
F’ihinrere hamora
Ma sona, ma gbadura
B’ise tab’ ewu ba pe
Ma se alai de ’be.

Duro, duro fun Jesu
Ija na ki y’o pe;
Oni, ariwo ogun,
Ola, orin ’segun,
Eni t’o ba si segun,
Y’o gba ade iye
Y’o ma ba Oba Ogo
Joba titi lailai…Amin