Nítorí pé ọjọ́ kan péré ninu àgbàlá rẹ, ṣe anfaani ju ẹgbẹrun ọjọ́ níbòmíràn lọ.@Orin Dafidi 84:10
aworan
Henry F. Lyte (1793–1847)

Henry F. Lyte, Spirit of the Psalms 1834 (Pleasant Are Thy Courts Above). .

Maidstone, Walter B. Gilbert, 1863 (🔊 pdf nwc)

aworan
Walter B. Gilbert
1829–1910

Bugbe Re ti l’ewa to!
N’ ile mole at’ ife,
Bugbe Re ti l’ewa to!
Laiye ese at’ osi.
Okan mi n fa ni to to
Fun idapo enia Re
Fun imole oju Re
Fun ekun Re Olorun

A yo ba awon eiye
Ti nfo yi pepe Re ka;
Ayo okan t’o simi
L’aiya Baba l’o poju!
Gege b’adaba Noa
Ti ko r’ibi simi le,
Nwon pada sodo Baba
Nwon si nyo titi aiye

Nwon ko simi iyin won,
Ninu aiye osi yi;
Omi nsun ni aginju,
Manna nt’orun wa fun won,
Nwon nlo lat’ipa de’pa,
Titi nwon fi yo si O;
Nwon si wole l’ese Re,
T’o mu won la ewu ja.

Baba je ki njere be
S’amona mi laiye yi,
F’ore-ofe pa mi mo
Fun mi l’aye lodo Re:
Iwo l’Orun at’ Asa
To okan isina mi;
Iwo l’Orisun ore
Ro ojo Re sori mi.