O si fi odò omi ìye kan han mi, ti o mọ́ bi kristali, ti nti ibi itẹ́ Ọlọrun ati ti Ọdọ-Agutan jade wá.@Ifihan 22:1
retrato
Robert Lowry (1826-1899)

Robert Lowry, 1864 (Shall We Gather at the River?) (🔊 pdf nwc). .

A o pa de leti odo,
T’ese angeli ti te;
T’o mo gara bi kristali;
Leba ite olorun?

Egbe

A o pade leti odo
Odo didan, odo didan na
Pel’ awon mimo leba odo
T’o nsan leba ite ni.

Leti bebe odo na yi
Pel’ Olusaguntan wa,
A o ma rin a o ma sin
B’a ti ntele ’pase Re.

Egbe

K’a to de odo didan naa,
A o s’eru wa kale
Jesu y’o gba eru ese
Awon ti y’o de l’ade.

Egbe

Nje l’eba odo tutu na,
A o r’oju Olugbala;
Emi wa ki o pinya mo
Yi o korin ogo Re.

Egbe